lundi 1 décembre 2014

IPADE AKINLABI TI IPARI OSU K'OKANLA (30 /Nov/ 2014

Eku dede iwoyi o,eyin baba ,momo, egbon mi 'lokunrin l'obinrin ati eyin elegbe mi

Eleyi ni abajade ipade AKINLABI elekan losu ti ama nse ti oko awa idile mererin ti aje olomo baba kanna papo ,Idile Aremo ati Idile Lagboye ati Idile Alabi pelu Idile Ejalonibu ti won je Idile olugb' alejo ti osu yi.

Awon Baba ti won fun wa ni oro isiti,. gba gbogbo idile ni imoran pe ki atubo mura si ifowosowopo laarin idile mereerin .Nitori pe ti aba se ara wa lokan kosi ibi tiwon koti ni maa fun wa ni ibowo ati etoo to oba tosi wa ,kosi ni si enikankan ti yoo le yan wa je.
 Won tun te siwaju ninu oro won pe lati igba aye awon Baba wa ti won ti reko ja lo ni ipade idile mereerin yi tiwa ,Ti kosi baje lori won nigba naa lohun kosi gbodo baje lori ti awon naa pelu , eleyi yoo si je anfaani ti opeye fun awon omo tiwon tun nbo leyin lati je ki ajosepo yii maa losiwaju sii. Opolopo anfaani si wa nibi ki ajo ma pade lati se ajosepo yi ti yoo si mu ilosiwaju ba idile ati igbesi aye enikookan wa paapa julo igbesi aye awon omo wa ti won yoo gba ipo wa nigba ti awa naa ba lo tan.

Baba tun gba wa ni imoran wipe ki amojuto awon omo wa ti anbi,ki ama se je ki won rare rara nipa fifi won si ile iwe tabi ile k'ewu,ti won koba s'ilo si ile iwe mo ki ajowo fiwon si enu ekose tabi ki adawon ni oko owo,Ki ale jere won l'Ojo ogbo wa ati ki ojo ola won le dara ki won ma ba ya omo k'omo ti nba orukoebi tabi idile je lehin wa ola.


Oro tun waye lori awon momo ati awon omo wa tiwon wa nile oko pe Akinlabi nbe pelu won lati duro tiwon lori awon idiwo kookan  tabi ekeji ti won ba ni ni ile oko won,Won wa luuwon l'ogo enu wipe eleyi ko gba won laaye lati ma ma se dede nipa eto ti oto siwon lati se si oko won ati idile oko won bakanna.
Fun ekunrere alaye,eje ki ajo pade ni ipade AKINLABI eyi ti nbo, ti iko idile aremo ma gba alejo awon idile meta t'oku ni ojo Isinmi keji ti otele odun tuntun ti ama kosi ni aipe yii  ,ni 11 Janvier 2015 Ki olorun oba alaanu ninu anu re je ki oju wa maa rodun o,Ao se opolopo odun laye o Amin!.

Ipade yi yoo waye ni ile aremo iwaju mairie Koumassi.Ni ojo yi kanna ni ao se adura ibere odun ti amanse  pelu awon alufa tiwon yoo bawa se adura gegebi ise wa ni odoodun,  owo ti ama nda fun eto adura yi je Apo Maarun cfa (5000 Frs cfa) Ki ama gbagbe o, pipeju gbogbo wa se pataki pupo ni ojo yi nitori adura longba agbara ko.
Aaye ati ma da owo yi ti si sile fun eni ti oba ti setan, lati ipade ojo isinmi ti nbo yi ( 6 Dec. 2014) Olorun yoo maa ranwa se o Amin!

Aucun commentaire:

Enregistrer un commentaire